ERE NLA BE LORUN FUN AWON TO NSIN OLUWA
Olorun so fun Jeremiah ki o soro si Isreali ti o kehin si ase re, Olorun je ki Jeremiah mo pe, yiyan an fun iru ise yi kii se asise bikose ohun ti o ti wa latete kose. Olorun so fun Jeremiah ‘Ki emi o to da o ni inu, emi ti mo o, ki iwo ki o si ti inu jade wa ni emi ti so o di mimo, emi si ya o soto lati je Wolii fun awon orile-ede. Emi si wipe Oluwa Olorun sa wo o, emi ko mo oro so nitori omode ni emi. Sugbon Oluwa wi fun mi pe, ma wi pe omode ni emi sugbon iwo o lo sodo enikeni ti emi o ran o si, ati ohunkohun ti emi o pase fun o ni iwo o se, ma beru niwaju won nitori emi wa pelu re lati gba o, ni Oluwa wi
(Jeremiah 1:5-8)
EKO
O je ohun ti o dara lati sin Olorun, sise bee ko ni abamo, awon iranse Olorun ni atilehin olori ogun won, Olorun alagbara aseyori won si daju. Ere fun awon ti a yan fun ise Olorun ko pin ni aye yi nikan sugbon yi o tun wa ni orun titi laelae, nitorina enikeni ti o ba nsise kan tabi omiran ni agbala Olorun, ni lati mokan le lati see tokan tokan ki o te Olorun lokan, niwon igbati ere won yi o duro ni aye ati ni orun.
ADURA
Olorun olufe, mo gba ore-ofe ati igboya re lati le tesiwaju ninu ise re, jowo ran mi lowo lati le sise ti yio te o lorun, je ki ere mi ki o maa dun, ki o si mu ere wa fun ijoba re, mase je ki ise ife mi jasi asan, ka mi ye ni ijoba re, si je ki ere mi duro. Ni oruko Jesu Kristi ni mo beere. Amin.
